Máàkù 10:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà, Jésù kúrò ní Kapanámù. Ó gba gúsù wá sí agbègbè Jùdíà, títí dé ìlà oòrùn odò Jọ́dánì. Bí i ti àtẹ̀yìnwá, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kọ́ wọn pẹ̀lú bí i ìṣe rẹ̀.

2. Àwọn Farisí kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”

3. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún un yín nípa ìkọ̀sílẹ̀.”

4. Wọ́n dáhùn pé, “Mósè yọ̀ǹda ìkọ̀sílẹ̀. Ohun tí ọkùnrin náà yóò ṣe ni kí ó fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, lẹ́yìn èyí, ààyè wà láti kọ obìnrin náà sílẹ̀.”

5. Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Mósè kọ òfin yìí fun un yín nítorí ẹ jẹ́ ọlọ́kàn líle.

6. Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo.

7. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì faramọ́ aya rẹ̀.

8. Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í tún ṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo.

Máàkù 10