9. Nígbà tí Jésù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà á sí i, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.”
10. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ-ọ̀dọ̀ náà tí ń sàìsàn, ara rẹ̀ ti dá
11. Ní ijọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Náínì: àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.
12. Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsí i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
13. Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”
14. Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ àga pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”
15. Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
16. Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!”
17. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Jùdéà, àti gbogbo agbégbé tí ó yí i ká.