Lúùkù 4:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú wọ́n ru ṣùṣù,

29. Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè taari rẹ̀ ní ògèdèǹgbé.

30. Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrin wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.

31. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.

32. Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàsẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Lúùkù 4