Lúùkù 23:39-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kírísítì, gba ara rẹ àti àwa là.”

40. Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?

41. Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwá ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”

42. Ó sì wí pé, “Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ.”

43. Jésù sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónì-ín ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè!”

Lúùkù 23