35. Àwọn ènìyàn sì dúró ń wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kírísítì, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”
36. Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un.
37. Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ́ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”
38. Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Gíríkì, àti ti Látínì, àti tí Hébérù: ÈYÍ NI ỌBA ÀWỌN JÚÙ.
39. Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kírísítì, gba ara rẹ àti àwa là.”
40. Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?
41. Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwá ṣe ni à ń jẹ: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”
42. Ó sì wí pé, “Jésù, rántí mi nígbà tí ìwọ́ bá dé ìjọba rẹ.”
43. Jésù sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónì-ín ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Párádísè!”
44. Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́.