15. Àti Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsí i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀.
16. Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.”
17. (Ṣùgbọ́n kò lè ṣàì dá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)
18. Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Bárábà sílẹ̀ fún wa!”
19. Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.
20. Pílátù sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jésù sílẹ̀.
21. Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélèbú, kàn án mọ àgbélèbú!”
22. Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kínni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”
23. Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélèbú, Ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀.
24. Pílátù sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́.
25. Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.
26. Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Símónì ara Kírénè, tí ó ń ti ìgbéríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélèbú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jésù.
27. Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún
28. Ṣùgbọ̀n Jésù yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálémù, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.
29. Nítorí kíyèsí i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fúnni mu rí!’
30. Nígbà náà ni“ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kékèké pé,“Bò wá mọ́lẹ̀!” ’
31. Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kínni a ó ṣe sára gbígbẹ?”
32. Àwọn méjì mìíràn bákàn náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa.