Léfítíkù 27:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́.

15. Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀.

16. “ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n sètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n ómà èso bárílì.

17. Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó yà ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọ tẹ́lẹ̀ náà ni kí o san.

18. Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù.

19. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdá márùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀.

20. Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tàá fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́.

21. Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún Olúwa. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà.

22. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa.

23. Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí Olúwa.

24. Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni ín, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á.

Léfítíkù 27