Léfítíkù 25:40-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrin yín: kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀.

41. Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní bàbá wọn.

42. Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.

43. Ẹ má ṣe rorò mọ́ wọn: ṣùgbọ́n ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín.

Léfítíkù 25