11. Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.
12. Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà.
13. “ ‘Ní ọdún idásílẹ̀ yìí, kí olúkúlùkù gbà ohun ìní rẹ̀ padà.
14. “ ‘Bí ẹ bá ta ilẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín tàbí bí ẹ bá ra èyíkéyí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ.
15. Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tó kù láti kórè.