4. Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá àtùpà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójojúmọ́.
5. “Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdáméjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹfà (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan.
6. Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fàmẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó gòólù bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.
7. Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ ọrẹ iná sísun fún Olúwa.
8. Búrẹ́dì yìí ni kí ẹ gbé wá ṣíwájú Olúwa nígbàkugbà, lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.