Léfítíkù 16:33-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ: yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.

34. “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Ísírẹ́lì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.”Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Léfítíkù 16