3. Nítorí ẹ̀yín ti kú, a sì fi iyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kírísítì nínú Ọlọ́run.
4. Nígbà tí Kírísítì, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.
5. Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyìí jásí ìbọ̀rìsà.
6. Lórí àwọn wọ̀nyìí ni ìbínú Ọlọ́run ńbọ̀ wá.
7. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apákan ayé yìí.