Kólósè 3:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ohunkóhun tí ẹ̀yín bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.

18. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.

19. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.

20. Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigi nínú Olúwa.

21. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.

22. Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrojú ṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣugbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run:

23. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn;

Kólósè 3