Jóṣúà 9:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn ará Hífì pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè se àdéhùn pẹ̀lú yín?”

8. “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Jóṣúà.Ṣùgbọ́n Jóṣúà béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yín ti wá?”

9. Wọ́n sì dáhùn pé: “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Éjíbítì,

10. àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Ámórì méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jọ́dánì, sí Síhónì ọba Héṣíbónì, àti Ógù ọba Básánì, tí wọ́n jọba ní Áṣítarótù.

11. Àwọn àgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’

12. Gbígbóná ní a mú oúnjẹ ní ojí nílé ní oji tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsinyí.

13. Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán. Asọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jínjìn.”

14. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa.

Jóṣúà 9