Jóṣúà 9:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nísinsinyí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”

26. Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọn kò sì pa wọ́n.

27. Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gíbíónì di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ní wọ́n wà títí di òní yìí.

Jóṣúà 9