11. Ta ni ó ṣáájú ṣe fún mi, tí èmi ìbáfi san-án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
12. “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara rẹ, tàbi ipárẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
13. Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ?Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì ẹ̀yìn rẹ.?
14. Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ?Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
15. Ipẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdépọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.
16. Èkíní fi ara mọ́ èkejì tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́kò lè wọ àárin wọn.