12. Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyànkí o sì rẹ ẹ sílẹ̀, kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13. Sin gbogbo wọn pa pọ̀ nínúerùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú
14. Nígbà náà ní èmi ó yàn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
15. “Ǹjẹ́ nísinsìnyí kíyèsí Béhámótì tímo dá pẹ̀lú rẹ: òun ha máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16. Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà níẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17. Òun a máa jù ìru rẹ̀ bí i igikédarì; Isan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.
18. Egungun rẹ̀ ní ògùsọ̀ idẹ;Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19. Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́Ọlọ́run; ṣíbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.