12. Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyànkí o sì rẹ ẹ sílẹ̀, kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13. Sin gbogbo wọn pa pọ̀ nínúerùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú
14. Nígbà náà ní èmi ó yàn ọ́ pé,ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
15. “Ǹjẹ́ nísinsìnyí kíyèsí Béhámótì tímo dá pẹ̀lú rẹ: òun ha máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16. Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà níẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.