Jóòbù 27:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kìyóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́; ó síjú rẹ̀, òun kò sì sí.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀,gbogbo rẹ̀ a lọ

20. Ẹ̀rù ńlá bàá bí omi ṣíṣàn;ẹ̀fúùfù ńlá jí i gbé lọ ní òru.

21. Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn gbé e lọ, òun sìlọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.

22. Nítorí pé Olódùmárè yóò kọ lù ú,kì yóò sì dá a sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

23. Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí ilórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.

Jóòbù 27