18. Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,àti bí ahéré tí olùsọ́ kọ́.
19. Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kìyóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́; ó síjú rẹ̀, òun kò sì sí.Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀,gbogbo rẹ̀ a lọ
20. Ẹ̀rù ńlá bàá bí omi ṣíṣàn;ẹ̀fúùfù ńlá jí i gbé lọ ní òru.
21. Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn gbé e lọ, òun sìlọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.
22. Nítorí pé Olódùmárè yóò kọ lù ú,kì yóò sì dá a sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
23. Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí ilórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.