4. Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,àwọn talákà àyé a sá pamọ́ pọ̀.
5. Kíyèsí i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ nínú ijùni àwọn talákà ijáde lọ sí iṣẹ́wọn; Wọ́n a tètè dìde láti wáohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fúnwọn àti fún àwọn ọmọ wọn
6. Olúkulùkù a sì ṣa ọkà oúnjẹ ẹranrẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
7. Ní hòòhò ni wọn má a sùn láìní aṣọ,tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
8. Ọ̀wàrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,wọ́n sì lẹ̀mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.
9. Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò níẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ talákà. Nítorí gbèsè