Jóòbù 20:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti ríojú-rere lọ́dọ̀ talákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.

11. Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbàèwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.

12. “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnurẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,

13. bí ó tilẹ̀ dá a sí, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀,tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,

14. Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ tiyípadà, ó jásí òróró pamọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;

Jóòbù 20