1. Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú Olúwa, Sàtánì sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú Olúwa.
2. Olúwa sì bi Sàtánì pé, Níbo ni ìwọ ti wá?Sàtánì sì dá Olúwa lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.”
3. Olúwa sì wí fún Sàtánì pé, “Ìwọ ha kíyèsí Jóòbù ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí èkejì rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòótọ́ tí ó sì dúró sinsin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kóríra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run-ún láìnídìí.”