Jóòbù 19:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Kí a fi kálàmú irin àti ti òjé kọwọ́n sínú àpáta fún láéláé.

25. Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáùndè miń bẹ láàyè àti pe òun ni yóò dìdedúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;

26. Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ arami run, síbẹ̀ láìsí ẹran ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,

27. Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojúmi ó sì wo, kì sì íṣe tiẹlòmìíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi.

28. “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a ṣáà rí ní ọwọ́ rẹ̀,’

29. Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù; nítorí ìbínú níímú ìjìyà wá nípa ìdàKí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”

Jóòbù 19