Jòhánù 17:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. “Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sáà fẹ́ràn mi ṣíwájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé.

25. “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi.

26. Mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mímọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”

Jòhánù 17