5. Àpapọ̀ ọdún tí Ádámù gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.
6. Nígbà tí Ṣétì pé àrùnlélọ́gọ́rùn ún ọdún (105), ó bí Énọ́sì.
7. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Énọ́sì, ó sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
8. Àpapọ̀ ọdún Ṣẹ́tì sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.
9. Nígbà tí Énọ́sì di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kénánì.
10. Lẹ́yìn tí ó bí Kénánì, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-lé-mẹ́ẹ̀dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.
11. Àpapọ̀ ọdún Énọ́sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.
12. Nígbà tí Kénánì di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Máhálálélì:
13. Lẹ́yìn tí ó bí Máhálálélì, ó wà láàyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rín ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbínrin.
14. Àpapọ̀ ọjọ́ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú.
15. Nígbà tí Máhálálélì pé ọmọ àrúnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Járédì.
16. Máhálálélì sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Járédì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
17. Àpapọ̀ iye ọdún rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.
18. Nígbà tí Járédì pé ọmọ ọgọ́jọ-ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Énọ́kù.
19. Lẹ́yìn èyí, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) ó sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìnrin.
20. Àpapọ̀ ọdún rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-méjìdínlógójì (962); ó sì kú.
21. Nígbà tí Énọ́kù pé ọmọ ọgọ́ta-ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Mètúsẹ́là.
22. Lẹ́yìn tí ó bí Mètúsẹ́là, Énọ́kù sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.