Jẹ́nẹ́sísì 5:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Máhálálélì sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Járédì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.

17. Àpapọ̀ iye ọdún rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú.

18. Nígbà tí Járédì pé ọmọ ọgọ́jọ-ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Énọ́kù.

19. Lẹ́yìn èyí, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) ó sì bí àwọn ọmọkúnrin àti ọmọbìnrin.

Jẹ́nẹ́sísì 5