1. Jósẹ́fù lọ sọ fún Fáráò pé, “Baba mi àti àwọn arákùnrin mi, pẹ̀lú agbo ẹran, agbo màlúù àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, ti dé láti ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì ti wà ní ilẹ̀ Gósénì báyìí.”
2. Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Fáráò.
3. Fáráò béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kín ni iṣẹ́ yín?”Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran”