Jẹ́nẹ́sísì 45:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Jósẹ́fù! Ṣe baba mi sì wà láàyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀.

4. Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Éjíbítì!

5. Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín.

6. Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀ ṣíwájú fún ọdún márùn ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè.

7. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú ọmọ yín sí fún-un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là.

8. “Nítorí náà kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ìhín bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba (Olùdámọ̀ràn) fún Fáráò, alákóso fún gbogbo ilé Fáráò àti alábojútó gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì.

Jẹ́nẹ́sísì 45