Jẹ́nẹ́sísì 42:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kénánì. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”

14. Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín!

15. Èyí sì ni a ó fi dán-an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Fáráò bá wà láàyè, ẹ kì yóò kùró níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá síbí.

16. Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú àtìmọ́lé, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Fáráò ti ń bẹ láàyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!”

17. Ó sì fi gbogbo wọn sínú àtìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta.

18. Ní ọjọ́ kẹ́ta, Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run:

19. Tí ó bá jẹ́ pé olótìítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọkan nínú yín dúró ni àtìmọ́lé ní ìhín, nígbà tí àwọn yókù u yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa.

20. Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má baà kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.

21. Wọ́n ń sọ ọ́ láàrin ara wọn wí pé, “Dájúdájú a ń jìyà nítorí ohun tí a ṣe sí Jósẹ́fù. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”

Jẹ́nẹ́sísì 42