Jẹ́nẹ́sísì 38:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Júdà, ọmọbìnrin Súà sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Júdà sì pé, ó gòkè lọ sí Tímínà, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hírà ará Ádúlámù tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ.

13. Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Támárì pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Tímínà láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.”

14. Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́. Ó sì jókòó sí ẹnu ibodè Énáímù, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Tímínà. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣélà ti dàgbà, ṣíbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.

15. Nígbà tí Júdà rí i, ó rò pé aṣẹ́wó ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀.

16. Láì mọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́, ó wí pé,“Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè bá mi lò pọ̀.”

17. Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ sí ọ láti inú agbo ẹran.”Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?”

18. Júdà sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?”Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípaṣẹ̀ rẹ̀.

19. Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà.

20. Nígbà náà ni Júdà fi ọmọ ewúrẹ́ náà rán ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí obìnrin náà, kí ó ba à lè rí àwọn nǹkan tí ó fi ṣe ìdúró gbà padà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀.

21. Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni aṣẹ́wó (aṣẹ́wó ibi ojúbọ òrìṣa) tí ó wà ní etí ọ̀nà Énáímù wà?”Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí aṣẹ́wó kankan níbí”

Jẹ́nẹ́sísì 38