13. Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírínwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.
14. Nígbà tí Ṣélà pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Ébérì.
15. Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ébérì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
16. Ébérì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pélégì.
17. Ébérì sì wà láàyè fún irínwó-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pélégì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
18. Nígbà tí Pélégì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Réù.
19. Ó sì tún wà láàyè fún igba-ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Réù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
20. Nígbà tí Réù pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Ṣérúgì.
21. Ó tún wà láàyè lẹ́yìn tí ó bí Ṣérúgì fún igba-ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.
22. Nígbà tí Ṣérúgì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Náhórì.
23. Ó sì wà láàyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Náhórì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
24. Nígbà tí Náhórì pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹ́rà.
25. Ó sì wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹ́rà, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.