Ísíkẹ́lì 31:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Fáráò Ọba Éjíbítì àti sí ìjọ rẹ̀:“ ‘Ta ní a le fi wé ọ ní ọlá ńlá?

3. Kíyèsí Ásíríà, tí ó jẹ́ òpépé igi niLébánónì ní ìgbà kan rí,pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣe ìji bo igbó náà;tí ó ga sókè,òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.

4. Omi mú un dàgbà sókè:orísun omi tí ó jìnlẹ̀ mú kí o dàgbà sókè;àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.

5. Nítorí náà ó ga sí òkè fíofíoju gbogbo igi orí pápá lọ;Ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i:àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

6. ẹyẹ ojú ọ̀runkọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀gbogbo ẹranko ìgbẹ́ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀;gbogbo orílẹ̀ èdè ńláń gbé abẹ́ ìjì rẹ̀.

7. Ọlá ńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́,pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀,nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.

Ísíkẹ́lì 31