Ísíkẹ́lì 20:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “ ‘Ṣùgbọ́n wọn sọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́ràn, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojú kọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Éjíbítì sílẹ̀, torí náà mo sọ pé ń ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, ń ó sì jẹ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Éjíbítì.

9. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn ń gbé láàrin wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Ísírẹ́lì nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì.

10. Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Éjíbítì mo sì mú wọn wá sínú ihà.

Ísíkẹ́lì 20