Ìfihàn 17:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ:

2. Ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pá àwọn tí ń gbé inú ayé.”

3. Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí ihà: mo sì rí obìnrin kan ó jòkòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.

Ìfihàn 17