Ẹ́sítà 8:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ṣérísésì fún Ésítà ayaba ní ilée Hámánì, ọ̀ta àwọn Júù. Módékáì sì wá síwájú ọba, nítorí Ẹ́sítà ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba.

2. Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ọ Hámánì ó sì fi fún Módékáì, Ẹ́sítà sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olóórí ilée Hámánì.

3. Ẹ́sítà sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hámánì ará Ágágì, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù.

4. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Ẹ́sítà ó sì dìde, ó dúró níwájúu rẹ̀.

Ẹ́sítà 8