Ẹ́sítà 1:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí olóógun láti Páṣíà àti Médíà, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

4. Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọlá ńlá a rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.

5. Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba se àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Súsà.

Ẹ́sítà 1