Ẹ́sírà 6:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Ádárì (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dáríúsì.

16. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—àwọn ìkógun, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.

17. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́run mẹ́rin akọ ọ̀dọ́ àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, obúkọ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

18. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpínsọ́wọ́ àti àwọn Léfì sì ẹgbẹẹgbẹ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè.

19. Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá.

Ẹ́sírà 6