Deutarónómì 32:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Jéṣúrúnì sanra tán ó sì tàpá;ìwọ ṣanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọo sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.

16. Wọ́n sì fi jowú pẹ̀lú ọlọ́run àjèjì i wọnwọ́n sì mú un bínú pẹ̀lú àwọn òrìṣà a wọn.

17. Wọ́n rúbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó sẹ̀sẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.

18. Ìwọ kò rántí Àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

19. Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ.

20. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.

Deutarónómì 32