Gbogbo ègun yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsí àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.