Deutarónómì 25:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàsán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

4. Má ṣe di akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí o bá ń pa ọkà.

5. Bí àwọn arákùnrin rẹ bá jọ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan wọn sì kú láìní ọmọkùnrin, opó rẹ̀ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ mìíràn tayọ ẹbí ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni yóò mú u ṣe aya, òun ni yóò sì ṣe ojúṣe ọkọ fún un.

6. Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má baá parẹ́ ní Ísírẹ́lì.

Deutarónómì 25