Àwọn Hébérù 13:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹ máa gbàdúrà fún wa: Nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo.

19. Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.

20. Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùsọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu ayérayé, àní Olúwa wa Jésù.

21. Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jésù Kírísítì; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín

Àwọn Hébérù 13