Ámósì 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Éjíbítì:

2. “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yànnínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ níyàfún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

3. Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀láìjẹ́ pé wọ́n ti gbà láti ṣe é?

4. Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbo,bí kò bá ní ohun ọdẹ?Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀bí kò bá rí ohun kan mú?

Ámósì 3