Àìsáyà 53:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedédé waa pa á lára nítorí àìsòdodo wa;ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lóríi rẹ̀,àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi múwa láradá.

6. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti sìnà lọ,ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀gbogbo àìṣedédé wa.

7. A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

Àìsáyà 53