9. Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,ẹ̀yin ahoro Jérúsálẹ́mù,nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,ó sì ti ra Jérúsálẹ́mù padà.
10. Olúwa yóò sí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ní ojú gbogbo orílẹ̀ èdè,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò ríìgbàlà Ọlọ́run wa.
11. Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìnínyìí!Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.
12. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúròtàbí kí ẹ ṣáré lọ;nítorí Olúwa ni yóò ṣíwájúu yín lọ,Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.