Àìsáyà 5:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoroláì kọ ọ́ láì rò ó,ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.Èmi yóò sì pàṣẹ fún kùrukùruláti má ṣe rọ̀jò sóríi rẹ̀.”

7. Ọgbà-àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogunni ilé Ísírẹ́lìàwọn ọkùnrin Júdàsì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni ó rí,Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ ẹkún ìpayínkeke.

8. Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́létí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kùtí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.

9. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sími létí“Ó dájú pé àwọn ilé ńlá ńláyóò di ahoro, àwọn ilé dára dára yóò wà láìní olùgbé.

10. Ọgbà-àjàrà sarè oko mẹwàá yóò múìkòkò wáìnì kan wá,nígbà tí òṣùwọ̀n hómérì kan yóò múagbọ̀n irúgbin kan wá.”

11. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìdení kùtùkùtù òwúrọ̀láti lépa ọtí líle,tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.

Àìsáyà 5