Àìsáyà 46:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
1. Bẹ́lì tẹríi rẹ̀ ba, Nébò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti diàjàgà sí wọn lọ́rùn,ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
2. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;wọn kò lè gba ẹrù náà,àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.