Àìsáyà 40:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.

8. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

9. Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Ṣíhónì,lọ sí orí òkè gíga.Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù,gbé ohùn rẹ ṣókè pẹ̀lú ariwo,gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlúu Júdà,“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

Àìsáyà 40