10. Wò ó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,apá rẹ̀ sì ń jọba fún un.Wò ó, ère rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀,àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.
11. Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan-àyàa rẹ̀;ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ da rí àwọn tí ó ní ọ̀dọ́.
12. Ta ni ó ti wọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀tí ó wọn àwọn ọ̀run?Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀-ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀nàti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?
13. Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,tàbí tí ó ti tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?