Àìsáyà 33:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀ èdè ni a kórègẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn bọ́ lù ú.

5. A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;Òun yóò kún Ṣíhónì pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6. Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

7. Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréréẹkún ní òpópónà;àwọn ikọ̀ àlàáfíà ṣunkún kíkorò.

Àìsáyà 33